Òwe 15:5-7

Òwe 15:5-7 YCB

Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn. Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀; ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.