Owe 15:5-7
Owe 15:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Aṣiwère gàn ẹkọ́ baba rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba feti si ibawi li o moye. Ni ile olododo li ọ̀pọlọpọ iṣura: ṣugbọn ninu òwò enia buburu ni iyọnu. Ete ọlọgbọ́n tan ìmọ kalẹ: ṣugbọn aiya aṣiwère kì iṣe bẹ̃.
Pín
Kà Owe 15Owe 15:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Òmùgọ̀ ọmọ á kẹ́gàn ìtọ́sọ́nà baba rẹ̀, ṣugbọn ọmọ tí ó gbọ́ ìkìlọ̀, ọlọ́gbọ́n ni. Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra, ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú. Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀, ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.
Pín
Kà Owe 15Owe 15:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn. Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀; ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.
Pín
Kà Owe 15