Owe 15:5-7

Owe 15:5-7 YBCV

Aṣiwère gàn ẹkọ́ baba rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba feti si ibawi li o moye. Ni ile olododo li ọ̀pọlọpọ iṣura: ṣugbọn ninu òwò enia buburu ni iyọnu. Ete ọlọgbọ́n tan ìmọ kalẹ: ṣugbọn aiya aṣiwère kì iṣe bẹ̃.