Òwe 15:15-17

Òwe 15:15-17 YCB

Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi, ṣùgbọ́n onínúdídùn ń jẹ àlàáfíà ní ìgbà gbogbo. Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù OLúWA sì wà ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu. Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.