Owe 15:15-17
Owe 15:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo ọjọ olupọnju ni ibi; ṣugbọn oninu-didùn njẹ alafia nigbagbogbo. Diẹ pẹlu ibẹ̀ru Oluwa, o san jù iṣura pupọ ti on ti iyọnu ninu rẹ̀. Onjẹ ewebẹ̀ nibiti ifẹ wà, o san jù abọpa malu lọ ati irira pẹlu rẹ̀.
Pín
Kà Owe 15Owe 15:15-17 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú, ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn. Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA, ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ. Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́, sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.
Pín
Kà Owe 15