ÌWÉ ÒWE 15:15-17

ÌWÉ ÒWE 15:15-17 YCE

Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú, ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn. Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA, ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ. Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́, sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.