Obìnrin oníwà rere gba ìyìn ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan. Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú. Olódodo tòótọ́ rí ìyè ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀. OLúWA kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù. Mọ èyí dájú pé: ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ láìjìyà. Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n. Ìfẹ́ inú olódodo yóò yọrí sí ohun rere ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú. Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i; òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní. Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i; ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura. Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà. Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú; ṣùgbọ́n olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù. Ẹni tí ó ń mú ìdààmú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán aláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọlọ́gbọ́n. Èso òdodo ni igi ìyè ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Bí àwọn olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé mélòó mélòó ni ènìyàn búburú àti àwọn tó dẹ́ṣẹ̀!
Kà Òwe 11
Feti si Òwe 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Òwe 11:16-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò