Owe 11:16-31

Owe 11:16-31 YBCV

Obinrin olore-ọfẹ gbà iyìn: bi alagbara enia ti igbà ọrọ̀. Alãnu enia ṣe rere fun ara rẹ̀: ṣugbọn ìka-enia nyọ ẹran-ara rẹ̀ li ẹnu. Enia buburu nṣiṣẹ ère-ẹ̀tan; ṣugbọn ẹniti ngbin ododo ni ère otitọ wà fun. Bi ẹniti o duro ninu ododo ti ini ìye, bẹ̃ni ẹniti nlepa ibi, o nle e si ikú ara rẹ̀. Awọn ti iṣe alarekereke aiya, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn inu rẹ̀ dùn si awọn aduroṣinṣin: Bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, enia buburu kì yio lọ laijiya, ṣugbọn iru-ọmọ olododo li a o gbàla. Bi oruka wura ni imu ẹlẹdẹ bẹ̃ni arẹwà obinrin ti kò moye. Kiki rere ni ifẹ inu awọn olododo; ṣugbọn ibinu ni ireti awọn enia buburu. Ẹnikan wà ti ntuka, sibẹ o mbi si i, ẹnikan si wà ti nhawọ jù bi o ti yẹ lọ, ṣugbọn kiki si aini ni. Ọkàn iṣore li a o mu sànra; ẹniti o mbomirin ni, ontikararẹ̀ li a o si bomirin pẹlu. Ẹniti o ba dawọ ọkà duro, on li enia o fibu: ṣugbọn ibukún yio wà li ori ẹniti o tà a. Ẹniti o fi ara balẹ wá rere, a ri oju-rere: ṣugbọn ẹniti o nwá ibi kiri, o mbọ̀wá ba a. Ẹniti o ba gbẹkẹle ọrọ̀ rẹ̀ yio ṣubu: ṣugbọn olododo yio ma gbà bi ẹka igi. Ẹniti o ba yọ ile ara rẹ̀ li ẹnu yio jogun ofo: aṣiwere ni yio ma ṣe iranṣẹ fun ọlọgbọ́n aiya. Eso ododo ni igi ìye; ẹniti o ba si yi ọkàn enia pada, ọlọgbọ́n ni. Kiye si i a o san a fun olododo li aiye: melomelo li enia buburu ati ẹ̀lẹṣẹ.