Owe 11:16-31

Owe 11:16-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Obìnrin oníwà rere gba ìyìn ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan. Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú. Olódodo tòótọ́ rí ìyè ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀. OLúWA kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù. Mọ èyí dájú pé: ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ láìjìyà. Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n. Ìfẹ́ inú olódodo yóò yọrí sí ohun rere ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú. Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i; òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní. Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i; ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura. Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà. Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú; ṣùgbọ́n olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù. Ẹni tí ó ń mú ìdààmú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán aláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọlọ́gbọ́n. Èso òdodo ni igi ìyè ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Bí àwọn olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé mélòó mélòó ni ènìyàn búburú àti àwọn tó dẹ́ṣẹ̀!

Owe 11:16-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Obinrin olore-ọfẹ gbà iyìn: bi alagbara enia ti igbà ọrọ̀. Alãnu enia ṣe rere fun ara rẹ̀: ṣugbọn ìka-enia nyọ ẹran-ara rẹ̀ li ẹnu. Enia buburu nṣiṣẹ ère-ẹ̀tan; ṣugbọn ẹniti ngbin ododo ni ère otitọ wà fun. Bi ẹniti o duro ninu ododo ti ini ìye, bẹ̃ni ẹniti nlepa ibi, o nle e si ikú ara rẹ̀. Awọn ti iṣe alarekereke aiya, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn inu rẹ̀ dùn si awọn aduroṣinṣin: Bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, enia buburu kì yio lọ laijiya, ṣugbọn iru-ọmọ olododo li a o gbàla. Bi oruka wura ni imu ẹlẹdẹ bẹ̃ni arẹwà obinrin ti kò moye. Kiki rere ni ifẹ inu awọn olododo; ṣugbọn ibinu ni ireti awọn enia buburu. Ẹnikan wà ti ntuka, sibẹ o mbi si i, ẹnikan si wà ti nhawọ jù bi o ti yẹ lọ, ṣugbọn kiki si aini ni. Ọkàn iṣore li a o mu sànra; ẹniti o mbomirin ni, ontikararẹ̀ li a o si bomirin pẹlu. Ẹniti o ba dawọ ọkà duro, on li enia o fibu: ṣugbọn ibukún yio wà li ori ẹniti o tà a. Ẹniti o fi ara balẹ wá rere, a ri oju-rere: ṣugbọn ẹniti o nwá ibi kiri, o mbọ̀wá ba a. Ẹniti o ba gbẹkẹle ọrọ̀ rẹ̀ yio ṣubu: ṣugbọn olododo yio ma gbà bi ẹka igi. Ẹniti o ba yọ ile ara rẹ̀ li ẹnu yio jogun ofo: aṣiwere ni yio ma ṣe iranṣẹ fun ọlọgbọ́n aiya. Eso ododo ni igi ìye; ẹniti o ba si yi ọkàn enia pada, ọlọgbọ́n ni. Kiye si i a o san a fun olododo li aiye: melomelo li enia buburu ati ẹ̀lẹṣẹ.

Owe 11:16-31 Yoruba Bible (YCE)

Obinrin onínúrere gbayì, ṣugbọn ọrọ̀ nìkan ni ìkà yóo ní. Ẹni tí ó ṣoore ṣe é fún ara rẹ̀, ẹni tí ó sì ń ṣìkà ó ń ṣe é fún ara rẹ̀. Owó ọ̀yà èké ni eniyan burúkú óo gbà, ṣugbọn ẹni tí ó bá hùwà òdodo yóo gba èrè òtítọ́. Ẹni tí ó dúró ṣinṣin lórí òdodo yóo yè, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lépa ibi yóo kú. Ẹni ìríra ni àwọn alágàbàgebè lójú OLUWA, ṣugbọn àwọn tí ọ̀nà wọn mọ́ ni ìdùnnú fún un. Dájúdájú ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà, ṣugbọn a óo gba àwọn olódodo là. Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni obinrin tí ó lẹ́wà tí kò ní làákàyè. Ìfẹ́ ọkàn olódodo a máa yọrí sí rere, ṣugbọn ìrètí eniyan burúkú a máa já sí ibinu. Ẹnìkan wà tíí máa ṣe ìtọrẹ àánú káàkiri, sibẹsibẹ àníkún ni ó ń ní, ẹnìkan sì wà tí ó háwọ́, sibẹsibẹ aláìní ni. Ẹni tí ó bá lawọ́ yóo máa ní àníkún, ẹni tí ó bá jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíràn balẹ̀, ọkàn tirẹ̀ náà yóo balẹ̀. Ẹni tí ó bá ń kó oúnjẹ pamọ́, yóo gba ègún sórí, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ta oúnjẹ, yóo rí ibukun gbà. Ẹni tí ó bá ń wá ire, yóo rí ojurere, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ibi, ibi yóo bá a. Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóo rẹ̀ dànù bí òdòdó, ṣugbọn olódodo yóo rú bí ewé tútù. Ẹni tí ó bá mú ìyọnu dé bá ìdílé rẹ̀ yóo jogún òfo, òmùgọ̀ ni yóo sì máa ṣe iranṣẹ ọlọ́gbọ́n. Èso olódodo ni igi ìyè, ṣugbọn ìwà aibikita fún òfin a máa paniyan. Bí a óo bá san ẹ̀san fún olódodo láyé, mélòó-mélòó ni ti eniyan burúkú ati ẹlẹ́ṣẹ̀.