Nehemiah 8:10-12

Nehemiah 8:10-12 YCB

Nehemiah wí pé, “Ẹ lọ kí ẹ gbádùn oúnjẹ tí ẹ yàn láàyò kí ẹ sì mú ohun dídùn, kí ẹ sì mú díẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tí kò ní. Ọjọ́ yìí, mímọ́ ni fún Olúwa wa. Ẹ má ṣe banújẹ́, nítorí ayọ̀ OLúWA ni agbára yín.” Àwọn ọmọ Lefi mú kí gbogbo ènìyàn dákẹ́ jẹ́, wọ́n wí pé, “Ẹ dákẹ́, nítorí mímọ́ ni ọjọ́ yìí. Ẹ má ṣe banújẹ́.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn lọ láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì fi ìpín oúnjẹ ránṣẹ́, wọ́n sì ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ńlá, nítorí báyìí àwọn òfin tí a sọ di mímọ́ fun wọn ti yé wọn.