Neh 8:10-12

Neh 8:10-12 YBCV

Nigbana ni o wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ jẹ ọ̀ra ki ẹ si mu ohun didùn, ki ẹ si fi apakan ipin ranṣẹ si awọn ti a kò pèse fun: nitori mimọ́ ni ọjọ yi fun Oluwa: ẹ máṣe banujẹ; nitori ayọ̀ Oluwa on li agbàra nyin. Bẹ̃ni awọn ọmọ Lefi mu gbogbo enia dakẹ jẹ, wipe, ẹ dakẹ, nitori mimọ́ ni ọjọ yi; ẹ má si ṣe banujẹ. Gbogbo awọn enia lọ lati jẹ ati lati mu ati lati fi ipin ranṣẹ, ati lati yọ ayọ̀ nla, nitoriti ọ̀rọ ti a sọ fun wọn ye wọn.