Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kapernaumu, ìlú kan ní Galili, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi. Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàṣẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ọkùnrin kan sì wà nínú Sinagọgu, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara, “Ó wí pé, kín ni ṣe tàwa tìrẹ, Jesu ará Nasareti? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”
Jesu sì bá a wí gidigidi, ó wí fun pe, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.” Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára.
Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “irú ẹ̀kọ́ kín ni èyí? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.” Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbègbè ilẹ̀ náà yíká.
Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú Sinagọgu, ó sì wọ̀ ilé Simoni lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Simoni dùbúlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀. Ó sì súnmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì náà sì fi sílẹ̀. O sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
Nígbà tí oòrùn sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn gbe àwọn aláìsàn, tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jesu; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá. Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn: nítorí tí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi náà.
Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jesu sì jáde lọ, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má ba à lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò lè ṣàìmá wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú: nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.” Ó sì ń wàásù nínú Sinagọgu ti Judea.