O si sọkalẹ wá si Kapernaumu, ilu kan ni Galili, o si nkọ́ wọn li ọjọ isimi.
Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitori taṣẹ-taṣẹ li ọ̀rọ rẹ̀.
Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu, ẹniti o li ẹmi aimọ́, o kigbe li ohùn rara,
O ni, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ iṣe; Ẹni Mimọ́ Ọlọrun.
Jesu si ba a wi, o ni, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade lara rẹ̀. Nigbati ẹmí eṣu na si gbé e ṣanlẹ li awujọ, o jade kuro lara rẹ̀, kò si pa a lara.
Hà si ṣe gbogbo wọn nwọn si mba ara wọn sọ, wipe, Ọ̀rọ kili eyi! nitori pẹlu aṣẹ ati agbara li o fi ba awọn ẹmi aimọ́ wi, nwọn si jade kuro.
Okikí rẹ̀ si kàn nibi gbogbo li àgbegbe ilẹ na yiká.
Nigbati o si dide kuro ninu sinagogu, o si wọ̀ ile Simoni lọ; ibà si ti dá iya aya Simoni bulẹ; nwọn si bẹ̀ ẹ nitori rẹ̀.
O si duro tirisi i, o ba ibà na wi; ibà si jọwọ rẹ̀ lọwọ: o si dide lọgan, o nṣe iranṣẹ fun wọn.
Nigbati õrùn si nwọ̀, gbogbo awọn ẹniti o ni olokunrun ti o li arunkarun, nwọn mu wọn tọ̀ ọ wá; o si fi ọwọ́ le olukuluku wọn, o si mu wọn larada.
Awọn ẹmi eṣu si jade lara ẹni pipọ pẹlu, nwọn nkigbe, nwọn si nwipe, Iwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọrun. O si mba wọn wi, kò si jẹ ki nwọn ki o fọhun: nitoriti nwọn mọ̀ pe Kristi ni iṣe.
Nigbati ilẹ si mọ́, o dide lọ si ibi ijù: ijọ enia si nwá a kiri, nwọn si tọ̀ ọ wá, nwọn si da a duro, nitori ki o má ba lọ kuro lọdọ wọn.
Ṣugbọn o si wi fun wọn pe, Emi kò le ṣaima wasu ijọba Ọlọrun fun ilu miran pẹlu: nitorina li a sá ṣe rán mi.
O si nwasu ninu sinagogu ti Galili.