Jesu bá lọ sí Kapanaumu, ìlú kan ní ilẹ̀ Galili. Ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí pẹlu àṣẹ ni ó fi ń sọ̀rọ̀. Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò, ó ní, “Háà! Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ ti Ọlọrun ni ọ́.”
Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí!” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbé ọkunrin náà ṣánlẹ̀ lójú gbogbo wọn, ó bá jáde kúrò lára rẹ̀, láì pa á lára.
Ẹnu ya gbogbo eniyan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Irú ọ̀rọ̀ wo ni èyí? Nítorí pẹlu àṣẹ ati agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì ń jáde!” Òkìkí Jesu sì kàn ká gbogbo ìgbèríko ibẹ̀.
Nígbà tí Jesu dìde kúrò ní ilé ìpàdé, ó wọ ilé Simoni lọ. Ìyá iyawo Simoni ń ṣàìsàn akọ ibà. Wọ́n bá sọ fún Jesu. Ó bá lọ dúró lẹ́bàá ibùsùn ìyá náà, ó bá ibà náà wí, ibà sì fi ìyá náà sílẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún wọn.
Nígbà tí oòrùn wọ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n ní oríṣìíríṣìí àrùn ni wọ́n mú wá sọ́dọ̀ Jesu. Ó bá gbé ọwọ́ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó wò wọ́n sàn. Àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan, wọ́n ń kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.”
Jesu ń bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé Jesu ni Mesaya.
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jesu jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí ẹnìkankan. Àwọn eniyan ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fẹ́ dá a dúró kí ó má kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Dandan ni fún mi láti waasu ìyìn rere ìjọba ọ̀run ní àwọn ìlú mìíràn, nítorí ohun tí Ọlọrun rán mi wá ṣe nìyí.”
Ni ó bá ń waasu ní gbogbo àwọn ilé ìpàdé ní Judia.