Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu,
tí í ṣe ọmọ Eli, tí í ṣe ọmọ Mattati,
tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Meliki,
tí í ṣe ọmọ Janai, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,
tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Amosi,
tí í ṣe ọmọ Naumu, tí í ṣe ọmọ Esili,
tí í ṣe ọmọ Nagai, tí í ṣe ọmọ Maati,
tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Ṣimei,
tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Joda,
Tí í ṣe ọmọ Joana, tí í ṣe ọmọ Resa,
tí í ṣe ọmọ Serubbabeli, tí í ṣe ọmọ Ṣealitieli,
tí í ṣe ọmọ Neri, tí í ṣe ọmọ Meliki,
tí í ṣe ọmọ Adi, tí í ṣe ọmọ Kosamu,
tí í ṣe ọmọ Elmadamu, tí í ṣe ọmọ Eri,
Tí í ṣe ọmọ Joṣua, tí í ṣe ọmọ Elieseri,
tí í ṣe ọmọ Jorimu, tí í ṣe Mattati,
tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Simeoni,
tí í ṣe ọmọ Juda, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,
tí í ṣe ọmọ Jonamu, tí í ṣe ọmọ Eliakimu,
Tí í ṣe ọmọ Melea, tí í ṣe ọmọ Menna,
tí í ṣe ọmọ Mattata, tí í ṣe ọmọ Natani,
tí í ṣe ọmọ Dafidi, tí í ṣe ọmọ Jese,
tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi,
tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,
Tí í ṣe ọmọ Amminadabu, tí í ṣe ọmọ Ramu,
tí í ṣe ọmọ Hesroni, tí í ṣe ọmọ Peresi,
tí í ṣe ọmọ Juda. Tí í ṣe ọmọ Jakọbu,
tí í ṣe ọmọ Isaaki, tí í ṣe ọmọ Abrahamu,
tí í ṣe ọmọ Tẹra, tí í ṣe ọmọ Nahori,
Tí í ṣe ọmọ Serugu, tí í ṣe ọmọ Reu,
tí í ṣe ọmọ Pelegi, tí í ṣe ọmọ Eberi,
tí í ṣe ọmọ Ṣela. Tí í ṣe ọmọ Kainani,
tí í ṣe ọmọ Arfaksadi, tí í ṣe ọmọ Ṣemu,
tí í ṣe ọmọ Noa, tí í ṣe ọmọ Lameki,
Tí í ṣe ọmọ Metusela, tí í ṣe ọmọ Enoku,
tí í ṣe ọmọ Jaredi, tí í ṣe ọmọ Mahalaleli,
tí í ṣe ọmọ Kainani. Tí í ṣe ọmọ Enosi,
tí í ṣe ọmọ Seti, tí í ṣe ọmọ Adamu,
tí í ṣe ọmọ Ọlọ́run.