Nigbati a si baptisi awọn enia gbogbo tan, o si ṣe, a baptisi Jesu pẹlu, bi o ti ngbadura, ọrun ṣí silẹ̀,
Ẹmí Mimọ́ si sọkalẹ si ori rẹ̀ li àwọ àdaba, ohùn kan si ti ọrun wá, ti o wipe, Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi; ẹniti inu mi dùn si gidigidi.
Jesu tikararẹ̀ nto bi ẹni ìwọn ọgbọ̀n ọdún, o jẹ (bi a ti fi pè) ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Eli,
Ti iṣe ọmọ Mattati, ti iṣe ọmọ Lefi, ti iṣe ọmọ Melki, ti iṣe ọmọ Janna, ti iṣe ọmọ Josefu,
Ti iṣe ọmọ Mattatai, ti iṣe ọmọ Amosi, ti iṣe ọmọ Naumu, ti iṣe ọmọ Esli, ti iṣe ọmọ Naggai,
Ti iṣe ọmọ Maati, ti iṣe ọmọ Mattatia, ti iṣe ọmọ Simei, ti iṣe ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Juda,
Ti iṣe ọmọ Joanna, ti iṣe ọmọ Resa, ti iṣe ọmọ Sorobabeli, ti iṣe ọmọ Salatieli, ti iṣe ọmọ Neri,
Ti iṣe ọmọ Melki, ti iṣe ọmọ Addi, ti iṣe ọmọ Kosamu, ti iṣe ọmọ Elmodamu, ti iṣe ọmọ Eri,
Ti iṣe ọmọ Jose, ti iṣe ọmọ Elieseri, ti iṣe ọmọ Jorimu, ti iṣe ọmọ Mattati, ti iṣe ọmọ Lefi,
Ti iṣe ọmọ Simeoni, ti iṣe ọmọ Juda, ti iṣe ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Jonani, ti iṣe ọmọ Eliakimu,
Ti iṣe ọmọ Melea, ti iṣe ọmọ Menani, ti iṣe ọmọ Mattata, ti iṣe ọmọ Natani, ti iṣe ọmọ Dafidi,
Ti iṣe ọmọ Jesse, ti iṣe ọmọ Obedi, ti iṣe ọmọ Boasi, ti iṣe ọmọ Salmoni, ti iṣe ọmọ Naassoni,
Ti iṣe ọmọ Aminadabu, ti iṣe ọmọ Aramu, ti iṣe ọmọ Esromu, ti iṣe ọmọ Faresi, ti iṣe ọmọ Juda,
Ti iṣe ọmọ Jakọbu, ti iṣe ọmọ Isaaki, ti iṣe ọmọ Abrahamu, ti iṣe ọmọ Tera, ti iṣe ọmọ Nakoru,
Ti iṣe ọmọ Saruku, ti iṣe ọmọ Ragau, ti iṣe ọmọ Faleki, ti iṣe ọmọ Eberi, ti iṣe ọmọ Sala,
Ti iṣe ọmọ Kainani, ti iṣe ọmọ Arfaksadi, ti iṣe ọmọ Semu, ti iṣe ọmọ Noa, ti iṣe ọmọ Lameki,
Ti iṣe ọmọ Metusala, ti iṣe ọmọ Enoku, ti iṣe ọmọ Jaredi, ti iṣe ọmọ Maleleeli, ti iṣe ọmọ Kainani,
Ti iṣe ọmọ Enosi, ti iṣe ọmọ Seti, ti iṣe ọmọ Adamu, ti iṣe ọmọ Ọlọrun.