Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan aginjù lẹ́bàá Òkun:
Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní gúúsù,
akógunjàlú kan wá láti aginjù,
láti ilẹ̀ ìpayà.
Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fihàn mí
ọlọ̀tẹ̀ ti tu àṣírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù.
Elamu kojú ìjà! Media ti tẹ̀gùn!
Èmi yóò mú gbogbo Ìpayínkeke dópin,
ni ó búra.
Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí,
ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti
obìnrin tí ń rọbí,
Mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́,
ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí.
Ọkàn mí dàrú,
ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi,
ìmọ́lẹ̀ tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí
ti wá di ìpayà fún mi.
Wọ́n tẹ́ tábìlì,
wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká,
wọ́n jẹ, wọ́n mu!
Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé,
ẹ fi òróró kún asà yín!
Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
“Lọ, kí o bojúwòde
kí o sì wá sọ ohun tí ó rí.
Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin,
àwọn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
tàbí àwọn tí ó gun ìbákasẹ,
jẹ́ kí ó múra sílẹ̀,
àní ìmúra gidigidi.”
Òun sì kígbe pé, kìnnìún kan;
“Láti ọjọ́ dé ọjọ́, olúwa mi, mo dúró lórí ilé ìṣọ́ ní ọ̀sán,
a sì fi mí ìṣọ́ mi ní gbogbo òru.
Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀ wá yìí
nínú kẹ̀kẹ́ ogun
àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin.
Ó sì mú ìdáhùn padà wá:
‘Babeli ti ṣubú, ó ti ṣubú!
Gbogbo àwọn ère òrìṣà rẹ̀
ló fọ́nká sórí ilẹ̀!’ ”
Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gún mọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà,
mo sọ ohun tí mo ti gbọ́
láti ọ̀dọ̀ OLúWA àwọn ọmọ-ogun,
láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Israẹli.