Àsọtẹ́lẹ̀ nípa aṣálẹ̀ etí òkun nìyí:
àjálù kan ń já bọ̀ láti inú aṣálẹ̀,
láti ilẹ̀ tí ó bani lẹ́rù,
ó ń bọ̀ bí ìjì líle tí ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá aṣálẹ̀.
Ìran tí a fi hàn mí yìí le:
Àwọn oníjàgídíjàgan lọ digun kó ìkógun,
abanǹkanjẹ́ sì ba nǹkan jẹ́.
Ẹ̀yin ará Elamu, ẹ gòkè lọ!
Ẹ̀yin ará Media, ẹ múra ogun!
Mo ti fòpin sí òṣé ati ìjìyà tí Babiloni kó bá gbogbo eniyan.
Nítorí náà, gbogbo ẹ̀gbẹ́ ní ń dùn mí,
gbogbo ara ní ń ro mí
bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́.
A tẹrí mi ba kí n má baà gbọ́ nǹkankan,
wọ́n dẹ́rù bà mí kí n má baà ríran.
Ọkàn mi dààmú, jìnnìjìnnì dà bò mí;
wọ́n ti sọ àfẹ̀mọ́júmọ́ tí mò ń retí di ìbẹ̀rù mọ́ mi lọ́wọ́.
Wọ́n tẹ́ tabili, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sílẹ̀
wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu.
Ariwo bá ta pé
“Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin ológun!
Ẹ fepo pa asà yín.”
Nítorí OLUWA wí fún mi pé:
“Lọ fi aṣọ́nà ṣọ́ ojú ọ̀nà,
kí ó máa kéde ohun tí ó bá rí.
Nígbà tí ó bá rí àwọn ẹlẹ́ṣin
tí wọn ń bọ̀ ní meji-meji, bí ó bá rí i
tí àwọn kan gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
tí àwọn kan gun ràkúnmí,
kí ó fara balẹ̀ dáradára,
kí ó dẹtísílẹ̀ dáradára.”
Ẹni tí ń ṣọ́nà kígbe pé:
“OLUWA mi, lórí ilé-ìṣọ́ ni èmi í dúró sí lojoojumọ,
níbi tí a fi mí ṣọ́, ni èmi í sì í wà ní òròòru.
Ẹ wò ó! Àwọn ẹlẹ́ṣin kan ń bọ̀,
wọ́n fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ní meji-meji!”
“Ẹ gbọ́! Ìlú Babiloni ti wó! Ó ti wó!
Pẹlu gbogbo àwọn oriṣa rẹ̀,
ó ti wó lulẹ̀ patapata.”
Ẹ̀yin eniyan mi tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀,
bí ẹni tẹ ọkà ní ibi ìpakà,
ohun tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun,
Ọlọrun Israẹli, ní mò ń kéde fun yín yìí.