Ọ̀RỌ-ìmọ niti ijù okun. Gẹgẹ bi ãja gusù ti ikọja lọ; bẹ̃ni o ti ijù wá, lati ilẹ ti o li ẹ̀ru.
Iran lile li a fi hàn mi; ọ̀dalẹ dalẹ, akoni si nkoni. Goke lọ, iwọ Elamu: dotì, iwọ Media; gbogbo ìmí-ẹ̀dùn inu rẹ̀ li emi ti mu da.
Nitorina ni ẹgbẹ́ mi ṣe kun fun irora: irora si ti dì mi mu, gẹgẹ bi irora obinrin ti nrọbi: emi tẹ̀ ba nigbati emi gbọ́ ọ: emi dãmu nigbati emi ri i.
Ọkàn mi nrò, ẹ̀ru dẹrùba mi: oru ayọ̀ mi li o ti sọ di ìbẹru fun mi.
Pèse tabili silẹ, yàn alore, jẹ, mu: dide, ẹnyin ọmọ-alade, ẹ kùn asà nyin.
Nitori bayi li Oluwa ti sọ fun mi, Lọ, fi ẹnikan ṣọ ọ̀na, jẹ ki o sọ ohun ti o ri.
O si ri kẹkẹ́ pẹlu ẹlẹṣin meji-meji, kẹkẹ́ kẹtẹkẹtẹ, kẹkẹ́ ibakasiẹ; o si farabalẹ̀ tẹtilelẹ gidigidi:
On si kigbe pe, kiniun kan: Oluwa mi, nigbagbogbo li emi nduro lori ile-iṣọ li ọsan, a si fi mi si iṣọ mi ni gbogbo oru:
Si kiyesi i, kẹkẹ́ enia kan ni mbọ̀ wá yi, pẹlu ẹlẹṣin meji-meji. On si dahun, o si wipe, Babiloni ṣubu, o ṣubu; ati gbogbo ere fifin òriṣa rẹ̀ li o wó mọlẹ.
Iwọ ìpaka mi, ati ọkà ilẹ ìpaka mi: eyi ti emi ti gbọ́ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ọgun, Ọlọrun Israeli li emi ti sọ fun ọ.