Nítorí náà, ó rán ọwọ́ tí ó kọ àkọlé yìí. “Èyí ni àkọlé náà tí a kọ: mene, mene, tekeli, peresini “Èyí ni nǹkan tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí: “ Mene: Ọlọ́run ti ṣírò ọjọ́ ìjọba rẹ. Ó sì ti mú u wá sí òpin. “ Tekeli: A ti gbé ọ lórí òṣùwọ̀n, ìwọ kò sì tó ìwọ̀n. “Peresini: A ti pín ìjọba rẹ a sì ti fi fún àwọn Media àti àwọn Persia.” Nígbà náà ni Belṣassari pàṣẹ pé kí a wọ Daniẹli ní aṣọ elése àlùkò, kí a sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, a sì kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí kẹta ní ìjọba rẹ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni a pa Belṣassari, ọba àwọn ara Kaldea. Dariusi ará Media sì gba ìjọba nígbà tí ó di ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́ta.
Kà Daniẹli 5
Feti si Daniẹli 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Daniẹli 5:24-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò