Nitorina ni a ṣe rán ọwọ na lati ọdọ rẹ̀ wá; ti a si fi kọ iwe yi. Eyiyi si ni iwe na ti a kọ, MENE, MENE, TEKELI, PERESINI. Eyi ni itumọ ohun na: MENE, Ọlọrun ti ṣirò ijọba rẹ, o si pari rẹ̀. TEKELI; A ti wọ̀n ọ wò ninu ọ̀ṣuwọn, iwọ kò si to. PERESINI; A pin ijọba rẹ, a si fi fun awọn ara Media, ati awọn ara Persia. Nigbana ni Belṣassari paṣẹ, nwọn si wọ̀ Danieli li aṣọ ododó, a si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a si ṣe ikede niwaju rẹ̀ pe, ki a fi i ṣe olori ẹkẹta ni ijọba. Loru ijọ kanna li a pa Belṣassari, ọba awọn ara Kaldea. Dariusi, ara Media si gba ijọba na, o si jẹ bi ẹni iwọn ọdun mejilelọgọta.
Kà Dan 5
Feti si Dan 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Dan 5:24-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò