DANIẸLI 5:24-31

DANIẸLI 5:24-31 YCE

Ìdí nìyí tí ó fi rán ọwọ́ kan jáde láti kọ àkọsílẹ̀ yìí. “Ohun tí a kọ náà nìyí: ‘MENE, MENE, TEKELI, PERESINI.’ Ìtumọ̀ rẹ̀ sì nìyí: MENE, Ọlọrun ti ṣírò àwọn ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti parí rẹ̀. TEKELI, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò sì kún ojú ìwọ̀n. PERESINI, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mede ati àwọn ará Pasia.” Beṣasari bá pàṣẹ, pé kí wọ́n gbé ẹ̀wù elése àlùkò, ti àwọn olóyè, wọ Daniẹli, kí wọ́n sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Wọ́n kéde ká gbogbo ìjọba pé Daniẹli ni igbá kẹta ní ìjọba. Ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an ni wọ́n pa Beṣasari, ọba àwọn ará Kalidea. Dariusi, ará Mede, ẹni ọdún mejilelọgọta sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.