Ìṣe àwọn Aposteli 2:42-45

Ìṣe àwọn Aposteli 2:42-45 YCB

Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn aposteli, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà. Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn; iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe. Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn; Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní sí.