Iṣe Apo 2:42-45

Iṣe Apo 2:42-45 YBCV

Nwọn si duro ṣinṣin ninu ẹkọ́ awọn aposteli, ati ni idapọ, ni bibu akara ati ninu adura. Ẹ̀rù si ba gbogbo ọkàn: iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi pipọ li a ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe. Gbogbo awọn ti o si gbagbọ́ wà ni ibikan, nwọn ni ohun gbogbo ṣọkan; Nwọn si ntà ohun ini ati ẹrù wọn, nwọn si npín wọn fun olukuluku, gẹgẹ bi ẹnikẹni ti ṣe alaini.