ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:42-45

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:42-45 YCE

Wọ́n ń fi tọkàntọkàn kọ́ ẹ̀kọ́ tí àwọn aposteli ń kọ́ wọn; wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n jọ ń jẹun; wọ́n jọ ń gbadura. Ẹ̀rù àwọn onigbagbọ wá ń ba gbogbo eniyan. Ọpọlọpọ ni iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe. Gbogbo àwọn onigbagbọ wà ní ibìkan náà. Wọ́n jọ ní ohun gbogbo ní àpapọ̀. Wọ́n ta gbogbo ohun tí wọ́n ní, wọ́n sì pín owó tí wọ́n rí láàrin ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ṣe aláìní sí.