Dafidi ọba sì dé Bahurimu, sì wò ó, Ọkùnrin kan ti ibẹ̀ jáde wá, láti ìdílé Saulu wá, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera: ó sì ń bú èébú bí o tí ń bọ̀. Ó sì sọ òkúta sí Dafidi, àti sí gbogbo ìránṣẹ́ Dafidi ọba, àti sí gbogbo ènìyàn, gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin sì wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti lọ́wọ́ òsì rẹ̀. Báyìí ni Ṣimei sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, “Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Beliali. OLúWA mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Saulu padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jẹ ọba; OLúWA ti fi ìjọba náà lé Absalomu ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.”
Abiṣai ọmọ Seruiah sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú olúwa mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.”
Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí OLúWA ti wí fún un pé: ‘Bú Dafidi!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”
Dafidi sì wí fún Abiṣai, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri: ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Benjamini yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé OLúWA ni ó sọ fún un. Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ́njú mi, OLúWA yóò sì fi ìre san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.”
Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣimei sì ń rìn òdìkejì òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókùúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀.