II. Sam 16:5-13

II. Sam 16:5-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

Dafidi ọba si de Bahurimu, si wõ, ọkunrin kan ti ibẹ̀ jade wá, lati idile Saulu wá, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Ṣimei, ọmọ Gera: o si nyan ẹ̃bu bi o ti mbọ̀. O si sọ okuta si Dafidi, ati si gbogbo iranṣẹ Dafidi ọba, ati si gbogbo awọn enia, gbogbo awọn alagbara ọkunrin si wà lọwọ ọtún rẹ̀ ati lọwọ osì rẹ̀. Bayi ni Ṣimei si wi nigbati o nyan ẽbu, Jade, jade, iwọ ọkunrin ẹjẹ, iwọ ọkunrin Beliali. Oluwa mu gbogbo ẹjẹ idile Saulu pada wá si ori rẹ, ni ipo ẹniti iwọ jọba; Oluwa ti fi ijọba na le Absalomu ọmọ rẹ lọwọ: si wõ, ìwa buburu rẹ li o mu eyi wá ba ọ, nitoripe ọkunrin ẹjẹ ni iwọ. Abiṣai ọmọ Seruia si wi fun ọba pe, Ẽṣe ti okú ajá yi fi mbu oluwa mi ọba? jẹ ki emi kọja, emi bẹ̀ ọ, ki emi si bẹ́ ẹ li ori. Ọba si wipe, Kili emi ni fi nyin ṣe, ẹnyin ọmọ Seruia? jẹ ki o ma bu bẹ̃, nitoriti Oluwa ti wi fun u pe: Bu Dafidi. Tani yio si wipe, Nitori kini iwọ fi ṣe bẹ̃? Dafidi si wi fun Abiṣai, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ọmọ mi ti o ti inu mi wá, nwá ẹmi mi kiri: njẹ melomelo ni ara Benjamini yi yio si ṣe? jọwọ rẹ̀, si jẹ ki o ma yan ẽbu; nitoripe Oluwa li o fi rán an. Bọ́ya Oluwa yio wo ipọnju mi, Oluwa yio si fi ire san a fun mi ni ipo ẽbu rẹ̀ loni. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si nlọ li ọ̀na, Ṣimei si nrìn li ẹba oke ti o wà li ẹgbẹ rẹ̀, o si nyan ẽbu bi o ti nlọ, o si nsọ ọ li okuta, o si nfún erupẹ.

II. Sam 16:5-13 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Dafidi ọba dé Bahurimu, ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera, láti inú ìdílé Saulu, jáde sí i, bí ó sì ti ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè lemọ́lemọ́. Ó ń sọ òkúta lu Dafidi ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn eniyan ńláńlá ati ọpọlọpọ eniyan mìíràn wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji Dafidi ọba. Ṣimei ń wí fún Dafidi bí ó ti ń ṣépè pé, “Kúrò lọ́dọ̀ mi! Kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìwọ apànìyàn ati eniyan lásán! Ìwọ tí o gba ìjọba mọ́ Saulu lọ́wọ́, OLUWA ń jẹ ọ́ níyà nisinsinyii, fún ọpọlọpọ eniyan tí o pa ninu ìdílé Saulu. OLUWA sì ti fi ìjọba rẹ fún Absalomu, ọmọ rẹ, ìparun ti dé bá ọ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́.” Abiṣai, ọmọ Seruaya wí fún ọba pé, “Kí ló dé tí òkú ajá lásánlàsàn yìí fi ń ṣépè lé ọba, oluwa mi? Jẹ́ kí n lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, kí n sì sọ orí rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ̀.” Ṣugbọn ọba dáhùn pé, “Kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin ọmọ Seruaya ninu ọ̀rọ̀ yìí. Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó sọ fún un pé kí ó máa ṣépè lé mi, ta ló ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè pé, kí ló dé tí ó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?” Dafidi sọ fún Abiṣai ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣebí ọmọ tèmi gan-an ni ó ń gbìyànjú láti pa mí yìí, kí ló dé tí ọ̀rọ̀ ti ará Bẹnjamini yìí fi wá jọ yín lójú. OLUWA ni ó ní kí ó máa ṣépè, nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣẹ́ ẹ. Bóyá OLUWA lè wo ìpọ́njú mi, kí ó sì fi ìre dípò èpè tí ó ń ṣẹ́ lé mi.” Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ń bá tiwọn lọ, Ṣimei sì ń tẹ̀lé wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji òkè náà, bí ó ti ń tẹ̀lé wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè, ó ń sọ òkúta lù ú, ó sì ń da erùpẹ̀ sí wọn lára.

II. Sam 16:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Dafidi ọba sì dé Bahurimu, sì wò ó, Ọkùnrin kan ti ibẹ̀ jáde wá, láti ìdílé Saulu wá, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera: ó sì ń bú èébú bí o tí ń bọ̀. Ó sì sọ òkúta sí Dafidi, àti sí gbogbo ìránṣẹ́ Dafidi ọba, àti sí gbogbo ènìyàn, gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin sì wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti lọ́wọ́ òsì rẹ̀. Báyìí ni Ṣimei sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, “Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Beliali. OLúWA mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Saulu padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jẹ ọba; OLúWA ti fi ìjọba náà lé Absalomu ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.” Abiṣai ọmọ Seruiah sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú olúwa mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.” Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí OLúWA ti wí fún un pé: ‘Bú Dafidi!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ” Dafidi sì wí fún Abiṣai, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri: ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Benjamini yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé OLúWA ni ó sọ fún un. Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ́njú mi, OLúWA yóò sì fi ìre san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.” Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣimei sì ń rìn òdìkejì òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókùúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀.