II. Sam 16:5-13

II. Sam 16:5-13 YBCV

Dafidi ọba si de Bahurimu, si wõ, ọkunrin kan ti ibẹ̀ jade wá, lati idile Saulu wá, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Ṣimei, ọmọ Gera: o si nyan ẹ̃bu bi o ti mbọ̀. O si sọ okuta si Dafidi, ati si gbogbo iranṣẹ Dafidi ọba, ati si gbogbo awọn enia, gbogbo awọn alagbara ọkunrin si wà lọwọ ọtún rẹ̀ ati lọwọ osì rẹ̀. Bayi ni Ṣimei si wi nigbati o nyan ẽbu, Jade, jade, iwọ ọkunrin ẹjẹ, iwọ ọkunrin Beliali. Oluwa mu gbogbo ẹjẹ idile Saulu pada wá si ori rẹ, ni ipo ẹniti iwọ jọba; Oluwa ti fi ijọba na le Absalomu ọmọ rẹ lọwọ: si wõ, ìwa buburu rẹ li o mu eyi wá ba ọ, nitoripe ọkunrin ẹjẹ ni iwọ. Abiṣai ọmọ Seruia si wi fun ọba pe, Ẽṣe ti okú ajá yi fi mbu oluwa mi ọba? jẹ ki emi kọja, emi bẹ̀ ọ, ki emi si bẹ́ ẹ li ori. Ọba si wipe, Kili emi ni fi nyin ṣe, ẹnyin ọmọ Seruia? jẹ ki o ma bu bẹ̃, nitoriti Oluwa ti wi fun u pe: Bu Dafidi. Tani yio si wipe, Nitori kini iwọ fi ṣe bẹ̃? Dafidi si wi fun Abiṣai, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ọmọ mi ti o ti inu mi wá, nwá ẹmi mi kiri: njẹ melomelo ni ara Benjamini yi yio si ṣe? jọwọ rẹ̀, si jẹ ki o ma yan ẽbu; nitoripe Oluwa li o fi rán an. Bọ́ya Oluwa yio wo ipọnju mi, Oluwa yio si fi ire san a fun mi ni ipo ẽbu rẹ̀ loni. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si nlọ li ọ̀na, Ṣimei si nrìn li ẹba oke ti o wà li ẹgbẹ rẹ̀, o si nyan ẽbu bi o ti nlọ, o si nsọ ọ li okuta, o si nfún erupẹ.