Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jesu Kristi Olúwa. Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo; Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́. Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú. Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́. Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde: Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fi àdúrà yín ràn wá lọ́wọ́. Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere tí a rí gbà nípa ìdáhùn sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.
Kà 2 Kọrinti 1
Feti si 2 Kọrinti 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 2 Kọrinti 1:2-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò