2 Kọrinti 1:2-11
2 Kọrinti 1:2-11 BMYO
Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jesu Kristi Olúwa. Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo. Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́. Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú. Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́. Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde. Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fi àdúrà yín ràn wá lọ́wọ́. Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere tí a rí gbà nípa ìdáhùn sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.





