KỌRINTI KEJI 1:2-11

KỌRINTI KEJI 1:2-11 YCE

Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba aláàánú ati Ọlọrun orísun ìtùnú, ẹni tí ó ń fún wa ní ìwúrí ninu gbogbo ìpọ́njú tí à ń rí, kí àwa náà lè fi ìwúrí fún àwọn tí ó wà ninu oríṣìíríṣìí ìpọ́njú nípa ìwúrí tí àwa fúnra wa ti níláti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti ní ìpín ninu ọpọlọpọ ìyà Kristi, bẹ́ẹ̀ náà ni a ní ọpọlọpọ ìwúrí nípasẹ̀ Kristi. Ṣugbọn bí a bá wà ninu ìpọ́njú, fún ìwúrí ati ìgbàlà yín ni. Bí a bá ní ìwúrí, ẹ̀yin náà yóo ní ìwúrí; ìwúrí yìí yóo sì kọ yín ní sùúrù nígbà tí ẹ bá ń jẹ irú ìyà tí àwa náà ń jẹ. Ìrètí wa lórí yín sì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, nítorí tí a mọ̀ pé bí a ti jọ ń jẹ irú ìyà kan náà, bẹ́ẹ̀ náà ni a jọ ní irú ìwúrí kan náà. Ẹ̀yin ará, a kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa ìpọ́njú tí ó tayọ agbára wa tí a ní ní Esia, Ìdààmú náà wọ̀ wá lọ́rùn tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí wa fi fẹ́rẹ̀ bọ́. A ṣe bí wọ́n tí dá wa lẹ́bi ikú ni. Kí á má baà gbẹ́kẹ̀lé ara wa, bíkòṣe Ọlọrun, ni ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Nítorí Ọlọrun níí jí òkú dìde. Ọlọrun ni ó yọ wá ninu ewu ńlá náà, òun ni yóo sì máa yọ wá. Òun ni a ní ìrètí ninu rẹ̀; yóo sì tún máa yọ wá, bí ẹ bá ń fi adura yín ràn wá lọ́wọ́. Nígbà náà ni ọpọlọpọ eniyan yóo ṣọpẹ́ nítorí ọpọlọpọ oore tí Ọlọrun ṣe fún wa.