1 Tẹsalonika 2:7-12

1 Tẹsalonika 2:7-12 YCB

Ṣùgbọ́n àwa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrín yín tí a sì ṣe ìtọ́jú yín. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ìfẹ́ inú rere sí yín, inú wa dùn jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìnrere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yín jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa. Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrín ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ìyànjú, ìtùnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkára rẹ̀.