I. Tes 2:7-12

I. Tes 2:7-12 YBCV

Ṣugbọn awa nṣe pẹlẹ lọdọ nyin, gẹgẹ bi abiyamọ ti ntọju awọn ọmọ on tikararẹ: Bẹ̃ gẹgẹ bi awa ti ni ifẹ inu rere si nyin, inu wa dun jọjọ lati fun nyin kì iṣe ihinrere Ọlọrun nikan, ṣugbọn ẹmí awa tikarawa pẹlu, nitoriti ẹnyin jẹ ẹni ọ̀wọ́n fun wa. Nitori ẹnyin ranti, ará, ìṣẹ́ ati lãlã wa: nitori awa nṣe lãlã li ọsán ati li oru, ki awa ko má bã di ẹrù ru ẹnikẹni ninu nyin, awa wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin. Ẹnyin si li ẹlẹri, ati Ọlọrun pẹlu, bi awa ti wà lãrin ẹnyin ti o gbagbọ́ ni mimọ́ iwà ati li ododo, ati li ailẹgan: Gẹgẹ bi ẹnyin si ti mọ̀ bi awa ti mba olukuluku nyin lo gẹgẹ bi baba si awọn ọmọ rẹ̀, a ngba nyin niyanju, a ntu nyin ninu, a si kọ́, Ki ẹnyin ki o le mã rìn ni yiyẹ Ọlọrun, ẹniti o npè nyin sinu ijọba ati ogo On tikararẹ.