TẸSALONIKA KINNI 2:7-12

TẸSALONIKA KINNI 2:7-12 YCE

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a wà ní ipò láti gba ìyìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Kristi. Ṣugbọn à ń ṣe jẹ́jẹ́ láàrin yín, àní gẹ́gẹ́ bí obinrin alágbàtọ́ tíí ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ tí ó ń tọ́jú. Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn wa fà sọ́dọ̀ yín; kì í ṣe ìyìn rere nìkan ni a fẹ́ fun yín, ṣugbọn ó dàbí ẹni pé kí á gbé gbogbo ara wa fun yín, nítorí ẹ ṣọ̀wọ́n fún wa. Ará, ẹ ranti ìṣòro ati làálàá wa, pé tọ̀sán-tòru ni à ń ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara wa, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára nígbà tí à ń waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín. Ẹ̀yin gan-an lè jẹ́rìí, Ọlọrun náà sì tó ẹlẹ́rìí wa pé, pẹlu ìwà mímọ́ ati òdodo ati àìlẹ́gàn ni a fi wà láàrin ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́; gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ pé bí baba ti rí sí àwọn ọmọ rẹ̀ ni a rí sí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín; tí à ń gbà yín níyànjú, tí à ń rọ̀ yín, tí à ń kìlọ̀ fun yín nípa bí ó ti yẹ kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín bí ẹni tí Ọlọrun pè sinu ìjọba ati ògo rẹ̀.