Ifi 16:2-3

Ifi 16:2-3 YBCV

Ekini si lọ, o si tú ìgo tirẹ̀ si ori ilẹ aiye; egbò kikẹ̀ ti o si dibajẹ si dá awọn enia ti o ni àmi ẹranko na, ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀. Ekeji si tú ìgo tirẹ̀ sinu okun; o si dabi ẹ̀jẹ okú enia: gbogbo ọkàn alãye si kú ninu okun.