Ifi 16:2-3
Ifi 16:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ekini si lọ, o si tú ìgo tirẹ̀ si ori ilẹ aiye; egbò kikẹ̀ ti o si dibajẹ si dá awọn enia ti o ni àmi ẹranko na, ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀. Ekeji si tú ìgo tirẹ̀ sinu okun; o si dabi ẹ̀jẹ okú enia: gbogbo ọkàn alãye si kú ninu okun.
Ifi 16:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Angẹli kinni lọ, ó bá da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu ayé. Ni egbò rírà tí ń rùn bá dà bo àwọn tí wọ́n ní àmì ẹranko náà ní ara, tí wọ́n sì ń júbà ère rẹ̀. Angẹli keji da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu òkun, ni òkun bá di ẹ̀jẹ̀, bí ẹ̀jẹ̀ ara òkú, gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun sì kú.
Ifi 16:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èkínní sì lọ, ó sì tú ago tirẹ̀ sí orílẹ̀ ayé: egbò kíkẹ̀ tí ó sì díbàjẹ́ sì dá àwọn ènìyàn tí ó ní ààmì ẹranko náà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀. Èkejì sì tú ago sínú Òkun; ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn: gbogbo ọkàn alààyè sì kú nínú Òkun.