Ifi 16
16
Àwọn Àwo tí Ó Kún fún Ibinu Ọlọrun
1MO si gbọ́ ohùn nla kan lati inu tẹmpili wá, nwi fun awọn angẹli meje nì pe, Ẹ lọ, ẹ si tú ìgo ibinu Ọlọrun wọnni si ori ilẹ aiye.
2Ekini si lọ, o si tú ìgo tirẹ̀ si ori ilẹ aiye; egbò kikẹ̀ ti o si dibajẹ si dá awọn enia ti o ni àmi ẹranko na, ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀.
3Ekeji si tú ìgo tirẹ̀ sinu okun; o si dabi ẹ̀jẹ okú enia: gbogbo ọkàn alãye si kú ninu okun.
4Ẹkẹta si tú ìgo tirẹ̀ sinu odò, ati si orisun awọn omi; nwọn si di ẹ̀jẹ.
5Mo si gbọ́ angẹli ti omi nì wipe, Olododo ni Iwọ Ẹni-Mimọ́, ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, nitoriti iwọ ṣe idajọ bayi.
6Nitoriti nwọn ti ta ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́ ati ti awọn woli silẹ, iwọ si fi ẹ̀jẹ fun wọn mu; eyiyi li o yẹ wọn.
7Mo si gbọ́ pẹpẹ nke wipe, Bẹ̃ni, Oluwa Ọlọrun Olodumare, otitọ ati ododo ni idajọ rẹ.
8Ẹkẹrin si tú ìgo tirẹ̀ sori õrùn; a si yọnda fun u lati fi iná jó enia lara.
9A si fi õru nla jo awọn enia lara, nwọn si sọ̀rọ-òdi si orukọ Ọlọrun, ẹniti o li agbara lori iyọnu wọnyi: nwọn kò si ronupiwada lati fi ogo fun u.
10Ẹkarun si tu ìgo tirẹ̀ sori ìtẹ ẹranko na; ilẹ-ọba rẹ̀ si ṣokunkun; nwọn si nge ahọn wọn jẹ nitori irora.
11Nwọn si sọ̀rọ-òdi si Ọlọrun ọrun nitori irora wọn ati nitori egbò wọn, nwọn kò si ronupiwada iṣẹ wọn.
12Ẹkẹfa si tú ìgo tirẹ̀ sori odò nla Eufrate; omi rẹ̀ si gbẹ, ki a le pese ọna fun awọn ọba ati ìla-õrùn wá.
13Mo si ri awọn ẹmí aimọ́ mẹta bi ọ̀pọlọ́, nwọn ti ẹnu dragoni na ati ẹnu ẹranko na ati ẹnu woli eke na jade wá.
14Nitori ẹmi èṣu ni wọn, ti nṣe iṣẹ-iyanu, awọn ti njade lọ sọdọ awọn ọba gbogbo ilẹ aiye, lati gbá wọn jọ si ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare.
15 Kiyesi i, mo mbọ̀ bi olè. Ibukún ni fun ẹniti nṣọna, ti o si npa aṣọ rẹ̀ mọ́, ki o má bã rìn ni ìhoho, nwọn a si ri itiju rẹ̀.
16O si gbá wọn jọ si ibikan ti a npè ni Har-mageddoni li ède Heberu.
17Ekeje si tú ìgo tirẹ̀ si oju ọrun; ohùn nla kan si ti inu tẹmpili jade lati ibi itẹ́, wipe, O pari.
18Mànamána si kọ, a si gbọ́ ohùn, ãrá si san, ìṣẹlẹ nla si ṣẹ̀, iru eyiti kò ṣẹ̀ ri lati igbati enia ti wà lori ilẹ, iru ìṣẹlẹ nla bẹ̃, ti o si lagbara tobẹ̃.
19Ilu nla na si pin si ipa mẹta, awọn orilẹ-ède si ṣubu: Babiloni nla si wá si iranti niwaju Ọlọrun, lati fi ãgo ọti-waini ti irunu ibinu rẹ̀ fun u.
20Olukuluku erekuṣu si salọ, a kò si ri awọn òke nla mọ́.
21Yinyín nla, ti ọkọ̃kan rẹ̀ to talenti ni ìwọ̀n, si bọ́ lù awọn enia lati ọrun wà: awọn enia si sọ̀rọ-òdi si Ọlọrun nitori iyọnu yinyín na; nitoriti iyọnu rẹ̀ na pọ̀ gidigidi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Ifi 16: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.