O. Daf 89:38-52

O. Daf 89:38-52 YBCV

Ṣugbọn iwọ ti ṣa tì, iwọ si korira, iwọ ti binu si Ẹni-ororo rẹ. Iwọ ti sọ majẹmu iranṣẹ rẹ di ofo: iwọ ti sọ ade rẹ̀ si ilẹ. Iwọ ti fa ọgba rẹ̀ gbogbo ya: iwọ ti mu ilu-olodi rẹ̀ di ahoro. Gbogbo awọn ti nkọja lọ li ọ̀na nfi ṣe ijẹ: on si di ẹ̀gan fun awọn aladugbo rẹ̀. Iwọ ti gbé ọwọ ọtún awọn ọta rẹ̀ soke; iwọ mu gbogbo awọn ọta rẹ̀ yọ̀. Iwọ si ti yi oju idà rẹ̀ pada pẹlu, iwọ kò si mu u duro li oju ogun. Iwọ ti mu ogo rẹ̀ tẹ́, iwọ si wọ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ-yilẹ. Ọjọ ewe rẹ̀ ni iwọ ke kuru; iwọ fi itìju bò o. Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o pa ara rẹ mọ́ lailai? ibinu rẹ yio ha jo bi iná bi? Ranti bi ọjọ mi ti kuru to; ẽse ti iwọ ha da gbogbo enia lasan? Ọkunrin wo li o wà lãye, ti kì yio ri ikú? ti yio gbà ọkàn rẹ̀ lọwọ isa-okú. Oluwa, nibo ni iṣeun-ifẹ rẹ atijọ wà, ti iwọ bura fun Dafidi ninu otitọ rẹ? Oluwa, ranti ẹ̀gan awọn iranṣẹ rẹ, ti emi nrù li aiya mi lati ọdọ gbogbo ọ̀pọ enia. Ti awọn ọta rẹ fi kẹgàn, Oluwa: ti nwọn fi ngàn ipasẹ Ẹni-ororo rẹ. Olubukún ni Oluwa si i titi lailai. Amin ati Amin.