ORIN DAFIDI 89:38-52

ORIN DAFIDI 89:38-52 YCE

Ṣugbọn nisinsinyii inú rẹ ti ru sí ẹni àmì òróró rẹ; o ti ta á nù, o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. O ti pa majẹmu tí o bá iranṣẹ rẹ dá tì, o ti ba adé rẹ̀ jẹ́, o ti fi wọ́lẹ̀. O ti wó gbogbo odi rẹ̀; o sì ti sọ ilé ìṣọ́ rẹ̀ di ahoro. Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ ní ń kó o lẹ́rù; ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀. O ti ran àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́; o ti mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ yọ̀ ọ́. Àní, o ti ba gbogbo ohun ìjà rẹ̀ jẹ́, o kò sì ràn án lọ́wọ́ lójú ogun. O ti gba ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀; o sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀. O ti gé ìgbà èwe rẹ̀ kúrú; o sì ti da ìtìjú bò ó. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí lae ni o óo máa fi ara pamọ́ fún mi? Yóo ti pẹ́ tó tí ibinu rẹ yóo máa jò bí iná? OLUWA, ranti bí ọjọ́ ayé ẹ̀dá ti gùn mọ, ati pé ẹ̀dá lásán ni ọmọ eniyan! Ta ló wà láyé tí kò ní kú? Ta ló lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́wọ́ agbára isà òkú? OLUWA, níbo ni ìfẹ́ rẹ ìgbàanì tí kì í yẹ̀ wà, tí o búra fún Dafidi pẹlu òtítọ́ rẹ? OLUWA, ranti bí èmi, iranṣẹ rẹ, ti di ẹni yẹ̀yẹ́; ati bí mo ti ń farada ẹ̀gàn àwọn eniyan, OLUWA àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ẹni tí o fi àmì òróró yàn ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń kẹ́gàn ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀. Ẹni ìyìn ni OLUWA títí lae!