O. Daf 78:32-55

O. Daf 78:32-55 YBCV

Ninu gbogbo wọnyi nwọn nṣẹ̀ siwaju, nwọn kò si gbà iṣẹ iyanu rẹ̀ gbọ́. Nitorina li o ṣe run ọjọ wọn li asan, ati ọdun wọn ni ijaiya. Nigbati o pa wọn, nigbana ni nwọn wá a kiri: nwọn si pada, nwọn bère Ọlọrun lakokò, Nwọn si ranti pe, Ọlọrun li apata wọn, ati Ọlọrun Ọga-ogo li Oludande wọn, Ṣugbọn ẹnu wọn ni nwọn fi pọ́n ọ, nwọn si fi ahọn wọn ṣeke si i. Nitori ọkàn wọn kò ṣe dẽde pẹlu rẹ̀, bẹ̃ni nwọn kò si duro ṣinṣin ni majẹmu rẹ̀. Ṣugbọn on, o kún fun iyọ́nu, o fi ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn, kò si run wọn: nitõtọ, nigba pupọ̀ li o yi ibinu rẹ̀ pada, ti kò si ru gbogbo ibinu rẹ̀ soke. Nitoriti o ranti pe, enia ṣa ni nwọn; afẹfẹ ti nkọja lọ, ti kò si tun pada wá mọ. Igba melo-melo ni nwọn sọ̀tẹ si i li aginju, ti nwọn si bà a ninu jẹ ninu aṣálẹ! Nitõtọ, nwọn yipada, nwọn si dan Ọlọrun wò, nwọn si ṣe aropin Ẹni-Mimọ́ Israeli. Nwọn kò ranti ọwọ rẹ̀, tabi ọjọ nì ti o gbà wọn lọwọ ọta. Bi o ti ṣe iṣẹ-àmi rẹ̀ ni Egipti, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ni igbẹ Soani. Ti o si sọ odò wọn di ẹ̀jẹ; ati omi ṣiṣan wọn, ti nwọn kò fi le mu u. O rán eṣinṣin sinu wọn, ti o jẹ wọn; ati ọpọlọ, ti o run wọn. O fi eso ilẹ wọn fun kokoro pẹlu, ati iṣẹ wọn fun ẽṣú. O fi yinyin pa àjara wọn, o si fi yinyin nla pa igi sikamore wọn. O fi ohun ọ̀sin wọn pẹlu fun yinyin, ati agbo-ẹran wọn fun manamana. O mu kikoro ibinu rẹ̀ wá si wọn lara, irunu ati ikannu, ati ipọnju, nipa riran angeli ibi sinu wọn. O ṣina silẹ fun ibinu rẹ̀; kò da ọkàn wọn si lọwọ ikú, ṣugbọn o fi ẹmi wọn fun àjakalẹ-àrun. O si kọlu gbogbo awọn akọbi ni Egipti, olori agbara wọn ninu agọ Hamu: Ṣugbọn o mu awọn enia tirẹ̀ lọ bi agutan, o si ṣe itọju wọn ni iju bi agbo-ẹran. O si ṣe amọna wọn li alafia, bẹ̃ni nwọn kò si bẹ̀ru: ṣugbọn okun bò awọn ọta wọn mọlẹ. O si mu wọn wá si eti ibi-mimọ́ rẹ̀, ani si òke yi ti ọwọ ọtún rẹ̀ ti rà. O tì awọn keferi jade pẹlu kuro niwaju wọn, o si fi tita okùn pinlẹ fun wọn ni ilẹ-ini, o si mu awọn ẹya Israeli joko ninu agọ wọn.