O. Daf 78:32-55
O. Daf 78:32-55 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ninu gbogbo wọnyi nwọn nṣẹ̀ siwaju, nwọn kò si gbà iṣẹ iyanu rẹ̀ gbọ́. Nitorina li o ṣe run ọjọ wọn li asan, ati ọdun wọn ni ijaiya. Nigbati o pa wọn, nigbana ni nwọn wá a kiri: nwọn si pada, nwọn bère Ọlọrun lakokò, Nwọn si ranti pe, Ọlọrun li apata wọn, ati Ọlọrun Ọga-ogo li Oludande wọn, Ṣugbọn ẹnu wọn ni nwọn fi pọ́n ọ, nwọn si fi ahọn wọn ṣeke si i. Nitori ọkàn wọn kò ṣe dẽde pẹlu rẹ̀, bẹ̃ni nwọn kò si duro ṣinṣin ni majẹmu rẹ̀. Ṣugbọn on, o kún fun iyọ́nu, o fi ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn, kò si run wọn: nitõtọ, nigba pupọ̀ li o yi ibinu rẹ̀ pada, ti kò si ru gbogbo ibinu rẹ̀ soke. Nitoriti o ranti pe, enia ṣa ni nwọn; afẹfẹ ti nkọja lọ, ti kò si tun pada wá mọ. Igba melo-melo ni nwọn sọ̀tẹ si i li aginju, ti nwọn si bà a ninu jẹ ninu aṣálẹ! Nitõtọ, nwọn yipada, nwọn si dan Ọlọrun wò, nwọn si ṣe aropin Ẹni-Mimọ́ Israeli. Nwọn kò ranti ọwọ rẹ̀, tabi ọjọ nì ti o gbà wọn lọwọ ọta. Bi o ti ṣe iṣẹ-àmi rẹ̀ ni Egipti, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ni igbẹ Soani. Ti o si sọ odò wọn di ẹ̀jẹ; ati omi ṣiṣan wọn, ti nwọn kò fi le mu u. O rán eṣinṣin sinu wọn, ti o jẹ wọn; ati ọpọlọ, ti o run wọn. O fi eso ilẹ wọn fun kokoro pẹlu, ati iṣẹ wọn fun ẽṣú. O fi yinyin pa àjara wọn, o si fi yinyin nla pa igi sikamore wọn. O fi ohun ọ̀sin wọn pẹlu fun yinyin, ati agbo-ẹran wọn fun manamana. O mu kikoro ibinu rẹ̀ wá si wọn lara, irunu ati ikannu, ati ipọnju, nipa riran angeli ibi sinu wọn. O ṣina silẹ fun ibinu rẹ̀; kò da ọkàn wọn si lọwọ ikú, ṣugbọn o fi ẹmi wọn fun àjakalẹ-àrun. O si kọlu gbogbo awọn akọbi ni Egipti, olori agbara wọn ninu agọ Hamu: Ṣugbọn o mu awọn enia tirẹ̀ lọ bi agutan, o si ṣe itọju wọn ni iju bi agbo-ẹran. O si ṣe amọna wọn li alafia, bẹ̃ni nwọn kò si bẹ̀ru: ṣugbọn okun bò awọn ọta wọn mọlẹ. O si mu wọn wá si eti ibi-mimọ́ rẹ̀, ani si òke yi ti ọwọ ọtún rẹ̀ ti rà. O tì awọn keferi jade pẹlu kuro niwaju wọn, o si fi tita okùn pinlẹ fun wọn ni ilẹ-ini, o si mu awọn ẹya Israeli joko ninu agọ wọn.
O. Daf 78:32-55 Yoruba Bible (YCE)
Sibẹsibẹ wọ́n tún dẹ́ṣẹ̀; pẹlu gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọn kò gbàgbọ́. Nítorí náà ó mú kí ọjọ́ ayé wọn pòórá bí afẹ́fẹ́; wọ́n sì lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìjayà. Nígbàkúùgbà tí ó bá ń pa wọ́n, wọn á wá a; wọn á ronupiwada, wọn á sì wá Ọlọrun tọkàntọkàn. Wọn á ranti pé Ọlọrun ni àpáta ààbò wọn, ati pé Ọ̀gá Ògo ni olùràpadà wọn. Ṣugbọn wọn kàn ń fi ẹnu wọn pọ́n ọn ni; irọ́ ni wọ́n sì ń pa fún un. Ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin lọ́dọ̀ rẹ̀; wọn kò sì pa majẹmu rẹ̀ mọ́. Sibẹ, nítorí pé aláàánú ni, ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kò sì pa wọ́n run; ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró, tí kò sì fi gbogbo ara bínú sí wọn. Ó ranti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ lásán tí ń fẹ́ kọjá lọ, tí kò sì ní pada mọ́. Ìgbà mélòó ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ninu ijù, tí wọ́n sì bà á lọ́kàn jẹ́ ninu aṣálẹ̀! Wọ́n dán an wò léraléra, wọ́n sì mú Ẹni Mímọ́ Israẹli bínú. Wọn kò ranti agbára rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ranti ọjọ́ tí ó rà wọ́n pada lọ́wọ́ ọ̀tá; nígbà tí ó ṣe iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní oko Soani. Ó sọ omi odò wọn di ẹ̀jẹ̀, tí wọn kò fi lè mu omi wọn. Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin sí wọn tí ó jẹ wọ́n, ati ọ̀pọ̀lọ́ tí ó pa wọ́n run. Ó mú kí kòkòrò jẹ èso ilẹ̀ wọn; eṣú sì jẹ ohun ọ̀gbìn wọn. Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́; ó sì fi òjò dídì run igi Sikamore wọn. Ó fi yìnyín pa mààlúù wọn; ó sì sán ààrá pa agbo aguntan wọn. Ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ lé wọn lórí: ìrúnú, ìkannú, ati ìpọ́njú, wọ́n dàbí ikọ̀ ìparun. Ó fi àyè gba ibinu rẹ̀; kò dá ẹ̀mí wọn sí, ó sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n. O kọlu gbogbo àkọ́bí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, àní, gbogbo àrẹ̀mọ ninu àgọ́ àwọn ọmọ Hamu. Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde bí agbo ẹran ó sì dà wọ́n láàrin aṣálẹ̀ bí agbo aguntan. Ó dà wọ́n lọ láìléwu, ẹ̀rù kò bà wọ́n; òkun sì bo àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀. Ó kó wọn wá sí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀, sí orí òkè tí ó ti fi agbára rẹ̀ gbà. Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde kí wọn ó tó dé ibẹ̀; ó pín ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn bí ohun ìní; ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli jókòó ninu àgọ́ wọn.
O. Daf 78:32-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú; nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́ O fi òpin sí ayé wọn nínú asán àti ọdún wọn nínú ìpayà. Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n, wọn yóò wá a kiri; wọn yóò fi ìtara yípadà sí i. Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn; wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un; Ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i, wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀. Síbẹ̀ ó ṣàánú; ó dárí àìṣedéédéé wọn jì òun kò sì pa wọ́n run nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà. Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro! Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò; wọ́n mú ẹni mímọ́ Israẹli bínú. Wọ́n kò rántí agbára rẹ̀: ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára, Ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn ní Ejibiti, àti iṣẹ́ ààmì rẹ̀ ni ẹkùn Ṣoani Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀; wọn kò lè mu láti odò wọn. Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run, àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun. Ó fi ọkà wọn fún láńtata, àwọn ìre oko wọn fún eṣú. Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ ó bá èso sikamore wọn jẹ́. Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín, agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná. Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára, ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú, nípa rírán angẹli apanirun sí wọn. Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀, òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú, ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn. Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin Ejibiti Olórí agbára wọn nínú àgọ́ Hamu Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran; ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù. Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n ṣùgbọ́n Òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀ òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní; ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.