Sibẹsibẹ wọ́n tún dẹ́ṣẹ̀; pẹlu gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọn kò gbàgbọ́. Nítorí náà ó mú kí ọjọ́ ayé wọn pòórá bí afẹ́fẹ́; wọ́n sì lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìjayà. Nígbàkúùgbà tí ó bá ń pa wọ́n, wọn á wá a; wọn á ronupiwada, wọn á sì wá Ọlọrun tọkàntọkàn. Wọn á ranti pé Ọlọrun ni àpáta ààbò wọn, ati pé Ọ̀gá Ògo ni olùràpadà wọn. Ṣugbọn wọn kàn ń fi ẹnu wọn pọ́n ọn ni; irọ́ ni wọ́n sì ń pa fún un. Ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin lọ́dọ̀ rẹ̀; wọn kò sì pa majẹmu rẹ̀ mọ́. Sibẹ, nítorí pé aláàánú ni, ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kò sì pa wọ́n run; ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró, tí kò sì fi gbogbo ara bínú sí wọn. Ó ranti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ lásán tí ń fẹ́ kọjá lọ, tí kò sì ní pada mọ́. Ìgbà mélòó ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ninu ijù, tí wọ́n sì bà á lọ́kàn jẹ́ ninu aṣálẹ̀! Wọ́n dán an wò léraléra, wọ́n sì mú Ẹni Mímọ́ Israẹli bínú. Wọn kò ranti agbára rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ranti ọjọ́ tí ó rà wọ́n pada lọ́wọ́ ọ̀tá; nígbà tí ó ṣe iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní oko Soani. Ó sọ omi odò wọn di ẹ̀jẹ̀, tí wọn kò fi lè mu omi wọn. Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin sí wọn tí ó jẹ wọ́n, ati ọ̀pọ̀lọ́ tí ó pa wọ́n run. Ó mú kí kòkòrò jẹ èso ilẹ̀ wọn; eṣú sì jẹ ohun ọ̀gbìn wọn. Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́; ó sì fi òjò dídì run igi Sikamore wọn. Ó fi yìnyín pa mààlúù wọn; ó sì sán ààrá pa agbo aguntan wọn. Ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ lé wọn lórí: ìrúnú, ìkannú, ati ìpọ́njú, wọ́n dàbí ikọ̀ ìparun. Ó fi àyè gba ibinu rẹ̀; kò dá ẹ̀mí wọn sí, ó sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n. O kọlu gbogbo àkọ́bí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, àní, gbogbo àrẹ̀mọ ninu àgọ́ àwọn ọmọ Hamu. Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde bí agbo ẹran ó sì dà wọ́n láàrin aṣálẹ̀ bí agbo aguntan. Ó dà wọ́n lọ láìléwu, ẹ̀rù kò bà wọ́n; òkun sì bo àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀. Ó kó wọn wá sí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀, sí orí òkè tí ó ti fi agbára rẹ̀ gbà. Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde kí wọn ó tó dé ibẹ̀; ó pín ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn bí ohun ìní; ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli jókòó ninu àgọ́ wọn.
Kà ORIN DAFIDI 78
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 78:32-55
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò