O. Daf 64

64
Adura Ààbò
1ỌLỌRUN, gbohùn mi ninu aroye mi: pa ẹmi mi mọ́ lọwọ ẹ̀ru ọta nì.
2Pa mi mọ́ lọwọ ìmọ ìkọkọ awọn enia buburu: lọwọ irukerudo awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ.
3Ẹniti npọ̀n ahọn wọn bi ẹnipe idà, ti nwọn si fa ọrun wọn le lati tafa wọn, ani ọ̀rọ kikoro:
4Ki nwọn ki o le ma tafà ni ìkọkọ si awọn ti o pé: lojiji ni nwọn tafa si i, nwọn kò si bẹ̀ru.
5Nwọn gba ara wọn niyanju li ọ̀ran buburu: nwọn gbìmọ ati dẹkun silẹ nikọ̀kọ; nwọn wipe, Tani yio ri wọn?
6Nwọn gbero ẹ̀ṣẹ; nwọn wipe, awa ti pari ero ti a gbà tan: ati ìro inu olukuluku wọn, ati aiya wọn, o jinlẹ.
7Ṣugbọn Ọlọrun yio tafà si wọn lojiji; nwọn o si gbọgbẹ.
8Bẹ̃ni ahọn wọn yio mu wọn ṣubu lu ara wọn: gbogbo ẹniti o ri wọn yio mì ori wọn.
9Ati gbogbo enia ni yio ma bẹ̀ru, nwọn o si ma sọ̀rọ iṣẹ Ọlọrun; nitoriti nwọn o fi ọgbọ́n rò iṣẹ rẹ̀.
10Olododo yio ma yọ̀ nipa ti Oluwa, yio si ma gbẹkẹle e; ati gbogbo ẹni-iduro-ṣinṣin li aiya ni yio ma ṣogo.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 64: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀