O. Daf 63

63
Wíwá Ọlọrun
Orin Dafidi, nigbati o wà li aginju Juda.
1ỌLỌRUN, iwọ li Ọlọrun mi; ni kutukutu li emi o ma ṣafẹri rẹ; ongbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi, ẹran-ara mi fà si ọ ni ilẹ gbigbẹ, ati ilẹ ti npongbẹ, nibiti omi kò gbe si.
2Bayi li emi ti wò ọ ninu ibi-mimọ́, lati ri agbara rẹ ati ogo rẹ.
3Nitori ti iṣeun-ifẹ rẹ san jù ìye lọ, ète mi yio ma yìn ọ.
4Bayi li emi o ma fi ibukún fun ọ niwọnbi mo ti wà lãye: emi o ma gbé ọwọ mi soke li orukọ rẹ.
5Bi ẹnipe ijà ati ọ̀ra bẹ̃ni yio tẹ ọkàn mi lọrun; ẹnu mi yio si ma fi ète ayọ̀ yìn ọ:
6Nigbati mo ba ranti rẹ lori ẹní mi, ti emi si nṣe aṣaro rẹ ni iṣọ oru.
7Nitoripe iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi, nitorina li ojiji iyẹ́-apa rẹ li emi o ma yọ̀.
8Ọkàn mi ntọ̀ ọ lẹhin girigiri: ọwọ ọtún rẹ li o gbé mi ró.
9Ṣugbọn awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run, nwọn o lọ si iha isalẹ-ilẹ.
10Nwọn o ti ọwọ idà ṣubu: nwọn o si ṣe ijẹ fun kọ̀lọkọlọ.
11Ṣugbọn ọba yio ma yọ̀ ninu Ọlọrun; olukuluku ẹniti o nfi i bura ni yio ṣogo: ṣugbọn awọn ti nṣeke li a o pa li ẹnu mọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 63: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀