O. Daf 65

65
Ìyìn ati Ọpẹ́
1ỌLỌRUN, iyìn duro jẹ de ọ ni Sioni: ati si ọ li a o mu ileri ifẹ nì ṣẹ.
2Iwọ ti ngbọ́ adura, si ọdọ rẹ ni gbogbo enia mbọ̀.
3Ọ̀ran aiṣedede bori mi: bi o ṣe ti irekọja wa ni, iwọ ni yio wẹ̀ wọn nù kuro.
4Alabukún-fun li ẹniti iwọ yàn, ti iwọ si mu lati ma sunmọ ọdọ rẹ, ki o le ma gbe inu agbala rẹ wọnni: ore inu ile rẹ yio tẹ́ wa lọrùn, ani ti tempili mimọ́ rẹ.
5Ohun iyanu nipa ododo ni iwọ fi da wa lohùn, Ọlọrun igbala wa: ẹniti iṣe igbẹkẹle gbogbo opin aiye, ati awọn ti o jina réré si okun.
6Nipa agbara rẹ̀ ẹniti o fi idi òke nla mulẹ ṣinṣin; ti a fi agbara dì li àmure:
7Ẹniti o pa ariwo okun mọ́ rọrọ, ariwo riru-omi wọn, ati gìrìgìrì awọn enia.
8Awọn pẹlu ti ngbe apa ipẹkun mbẹ̀ru nitori àmi rẹ wọnni: iwọ mu ijade owurọ ati ti aṣalẹ yọ̀.
9Iwọ bẹ aiye wò, o si bomi rin i: iwọ mu u li ọrọ̀, odò Ọlọrun kún fun omi: iwọ pèse ọkàn wọn, nigbati iwọ ti pèse ilẹ bẹ̃.
10Iwọ fi irinmi si aporo rẹ̀ pipọpìpọ: iwọ si tẹ́ ogulutu rẹ̀: iwọ fi ọwọ òjọ mu ilẹ rẹ̀ rọ̀: iwọ busi hihu rẹ̀.
11Iwọ fi ore rẹ de ọdun li ade; ọrá nkán ni ipa-ọ̀na rẹ.
12Papa-tutù aginju nkán: awọn òke kekèke fi ayọ̀ di ara wọn li àmure.
13Agbo ẹran li a fi wọ̀ pápá-tútù na li aṣọ: afonifoji li a fi ọka bò mọlẹ: nwọn nhó fun ayọ̀, nwọn nkọrin pẹlu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 65: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀