O. Daf 28:6-9

O. Daf 28:6-9 YBCV

Olubukún ni Oluwa, nitoriti o ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi. Oluwa li agbara ati asà mi; on li aiya mi gbẹkẹle, a si nràn mi lọwọ: nitorina inu mi dùn jọjọ: emi o si ma fi orin mi yìn i. Oluwa li agbara wọn, on si li agbara igbala ẹni-ororo rẹ̀. Gbà awọn enia rẹ là, ki o si busi ilẹ-ini rẹ: ma bọ́ wọn pẹlu, ki o si ma gbé wọn leke lailai.