O. Daf 28:6-9
O. Daf 28:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Olubukún ni Oluwa, nitoriti o ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi. Oluwa li agbara ati asà mi; on li aiya mi gbẹkẹle, a si nràn mi lọwọ: nitorina inu mi dùn jọjọ: emi o si ma fi orin mi yìn i. Oluwa li agbara wọn, on si li agbara igbala ẹni-ororo rẹ̀. Gbà awọn enia rẹ là, ki o si busi ilẹ-ini rẹ: ma bọ́ wọn pẹlu, ki o si ma gbé wọn leke lailai.
O. Daf 28:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni ìyìn ni OLUWA! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA ni agbára ati asà mi, òun ni mo gbẹ́kẹ̀lé; ó ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀; mo sì fi orin ìyìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. OLUWA ni agbára àwọn eniyan rẹ̀; òun ni ààbò ìgbàlà fún ẹni àmì òróró rẹ̀. Gba àwọn eniyan rẹ là, OLUWA, kí o sì bukun ilẹ̀ ìní rẹ. Jẹ́ olùṣọ́-aguntan wọn, kí o sì máa tọ́jú wọn títí lae.
O. Daf 28:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Alábùkún fún ni OLúWA! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. OLúWA ni agbára mi àti asà mi; nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀ àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un. OLúWA ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀ òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀. Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ; di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.