O. Daf 123:1-4

O. Daf 123:1-4 YBCV

IWỌ ni mo gbé oju mi soke si, iwọ ti ngbe inu ọrun. Kiyesi i, bi oju awọn iranṣẹkunrin ti ima wò ọwọ awọn baba wọn, ati bi oju iranṣẹ-birin ti ima wò ọwọ iya rẹ̀; bẹ̃li oju wa nwò Oluwa Ọlọrun wa, titi yio fi ṣãnu fun wa. Oluwa, ṣãnu fun wa, ṣãnu fun wa: nitori ti a kún fun ẹ̀gan pupọ̀-pupọ̀. Ọkàn wa kún pupọ̀-pupọ̀ fun ẹ̀gan awọn onirera, ati fun ẹ̀gan awọn agberaga.