O. Daf 123:1-4
O. Daf 123:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
IWỌ ni mo gbé oju mi soke si, iwọ ti ngbe inu ọrun. Kiyesi i, bi oju awọn iranṣẹkunrin ti ima wò ọwọ awọn baba wọn, ati bi oju iranṣẹ-birin ti ima wò ọwọ iya rẹ̀; bẹ̃li oju wa nwò Oluwa Ọlọrun wa, titi yio fi ṣãnu fun wa. Oluwa, ṣãnu fun wa, ṣãnu fun wa: nitori ti a kún fun ẹ̀gan pupọ̀-pupọ̀. Ọkàn wa kún pupọ̀-pupọ̀ fun ẹ̀gan awọn onirera, ati fun ẹ̀gan awọn agberaga.
O. Daf 123:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí, ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run Kíyèsi, bí ojú àwọn ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn, àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo OLúWA Ọlọ́run wa, títí yóò fi ṣàánú fún wa. OLúWA, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa; nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀. Ọkàn wa kún púpọ̀ fún ẹ̀gàn àwọn onírera, àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.

O. Daf 123:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ìwọ ni mo gbé ojú sókè sí, ìwọ tí o gúnwà ní ọ̀run. Wò ó, bí iranṣẹkunrin ti máa ń wo ojú oluwa rẹ̀, tí iranṣẹbinrin sì máa ń wo ojú oluwa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni à ń wo ojú OLUWA, Ọlọrun wa, títí tí yóo fi ṣàánú wa. Ṣàánú wa, OLUWA, ṣàánú wa, ẹ̀gàn yìí ti pọ̀ jù! Ẹ̀gàn àwọn onírera ti pọ̀ jù fún wa; yẹ̀yẹ́ àwọn onigbeeraga sì ti sú wa.