Owe 5:7-14

Owe 5:7-14 YBCV

Njẹ gbọ́ temi nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ki ẹnyin ki o máṣe yà kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. Takete kuro lọdọ rẹ̀, má si ṣe sunmọ eti ilẹkun ile rẹ̀: Ki iwọ ki o má ba fi ọlá rẹ fun ẹlomiran, ati ọdun rẹ fun ẹni-ìka; Ki a má ba fi ọrọ̀ rẹ fun ajeji enia; ki ère-iṣẹ ọwọ rẹ ki o má ba wà ni ile alejo. Iwọ a si ma kãnu ni ikẹhin rẹ̀, nigbati ẹran-ara ati ara rẹ ba parun. Iwọ a si wipe, emi ha ti korira ẹkọ́ to, ti aiya mi si gàn ìbawi: Ti emi kò gbà ohùn awọn olukọ́ mi gbọ́, tabi ki emi dẹti mi silẹ si awọn ti nkọ́ mi. Emi fẹrẹ wà ninu ibi patapata larin awujọ, ati ni ijọ.